Isaiah 3

Ìdájọ́ lórí i Jerusalẹmu àti Juda

1Kíyèsi i, Olúwa,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jerusalẹmu àti Juda
gbogbo ìpèsè oúnjẹ àti ìpèsè omi.
2Àwọn akíkanjú àti jagunjagun,
adájọ́ àti wòlíì,
aláfọ̀ṣẹ àti alàgbà,
3balógun àádọ́ta àti àwọn ènìyàn, onípò gíga
olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́
àti ògbójú oníṣègùn.

4“Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,
ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì
máa jẹ ọba lórí i wọn.”

5Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n
ọmọnìkejì wọn lójú
ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò
sí aládùúgbò rẹ̀.
Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà,
àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá.

6Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn
arákùnrin rẹ̀ mú,
nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,
“Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,
sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
7Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,
“Èmi kò ní àtúnṣe kan.
Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé,
ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”

8Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n
Juda ń ṣubú lọ,
ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,
láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
9Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,
wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu;
wọn ò fi pamọ́!
Ègbé ni fún wọn!
Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.

10Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,
nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn.
11Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn
A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.

12Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú
àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí.
Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà,
wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

13 Olúwa bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́
Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
14 Olúwa dojú ẹjọ́ kọ
àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,
ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
15Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú
tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?”
ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16 Olúwa wí pé,
“Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga,
wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,
tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,
tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ
pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn.
17Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni,
Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”
18Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá 19gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, 20gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn, 21òrùka ọwọ́ àti ti imú, 22àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́, 23Dígí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

24Dípò òórùn dídùn, òórùn búburú ni yóò wá,
okùn ni yóò wà dípò àmùrè,
orí pípá ni yóò dípò irun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́
aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.
25Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú,
àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.
26Àwọn bodè Sioni yóò sọkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀,
nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.
Copyright information for YorBMYO